Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #197 Translated in Yoruba

وَقَاتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ الدِّينُ لِلَّهِ ۖ فَإِنِ انْتَهَوْا فَلَا عُدْوَانَ إِلَّا عَلَى الظَّالِمِينَ
E gbogun ti won titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo. Esin ’Islam yo si wa (ni ominira) fun Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu iborisa), ko si ogun mo ayafi lori awon alabosi
الشَّهْرُ الْحَرَامُ بِالشَّهْرِ الْحَرَامِ وَالْحُرُمَاتُ قِصَاصٌ ۚ فَمَنِ اعْتَدَىٰ عَلَيْكُمْ فَاعْتَدُوا عَلَيْهِ بِمِثْلِ مَا اعْتَدَىٰ عَلَيْكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ
Osu owo fun osu owo. Awon nnkan owo si ni (ofin) igbesan. Nitori naa, enikeni ti o ba tayo enu-ala si yin, e gb’esan itayo enu-ala lara re pelu iru ohun ti o fi tayo enu-ala si yin. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu n be pelu awon oluberu (Re)
وَأَنْفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا تُلْقُوا بِأَيْدِيكُمْ إِلَى التَّهْلُكَةِ ۛ وَأَحْسِنُوا ۛ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ
E nawo fun ogun esin Allahu. Ki e si ma se fi owo ara yin fa iparun (nipa sisa fun ogun esin). E se rere. Dajudaju Allahu nifee awon oluse-rere
وَأَتِمُّوا الْحَجَّ وَالْعُمْرَةَ لِلَّهِ ۚ فَإِنْ أُحْصِرْتُمْ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ ۖ وَلَا تَحْلِقُوا رُءُوسَكُمْ حَتَّىٰ يَبْلُغَ الْهَدْيُ مَحِلَّهُ ۚ فَمَنْ كَانَ مِنْكُمْ مَرِيضًا أَوْ بِهِ أَذًى مِنْ رَأْسِهِ فَفِدْيَةٌ مِنْ صِيَامٍ أَوْ صَدَقَةٍ أَوْ نُسُكٍ ۚ فَإِذَا أَمِنْتُمْ فَمَنْ تَمَتَّعَ بِالْعُمْرَةِ إِلَى الْحَجِّ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ ۚ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ فِي الْحَجِّ وَسَبْعَةٍ إِذَا رَجَعْتُمْ ۗ تِلْكَ عَشَرَةٌ كَامِلَةٌ ۗ ذَٰلِكَ لِمَنْ لَمْ يَكُنْ أَهْلُهُ حَاضِرِي الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
E se asepe ise Hajj ati ‘Umrah fun Allahu. Ti won ba si se yin mo oju ona, e fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eyin ko si gbodo fa irun ori yin titi di igba ti eran ore naa yo fi de aye re. Enikeni ninu yin ti o ba je alaisan tabi inira kan n be ni ori re, o maa fi aawe tabi saraa tabi eran pipa se itanran (fun kikanju fa irun ori). Nigba ti e ba fokanbale (ninu ewu), enikeni ti o ba se ‘Umrah ati Hajj ninu osu ise Hajj, o maa fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eni ti ko ba ri (eran ore), ki o gba aawe ojo meta ninu (ise) hajj, meje nigba ti e ba dari wale. Iyen ni (aawe) mewaa t’o pe. Iyen wa fun eni ti ko si ebi re ni Mosalasi Haram. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le (nibi) iya
الْحَجُّ أَشْهُرٌ مَعْلُومَاتٌ ۚ فَمَنْ فَرَضَ فِيهِنَّ الْحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي الْحَجِّ ۗ وَمَا تَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ يَعْلَمْهُ اللَّهُ ۗ وَتَزَوَّدُوا فَإِنَّ خَيْرَ الزَّادِ التَّقْوَىٰ ۚ وَاتَّقُونِ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ
Hajj sise (wa) ninu awon osu ti A ti mo. Nitori naa, enikeni ti o ba se e ni oran-anyan lori ara re lati se Hajj ninu awon osu naa, ko gbodo si oorun ife, ese dida ati ariyanjiyan ninu ise Hajj. Ohunkohun ti e ba se ni rere, Allahu mo on. E mu ese irin-ajo lowo. Dajudaju ese irin-ajo t’o loore julo ni isora (nibi ese elomiiran ati agbe sise l’asiko ise Hajj). E beru Mi, eyin onilaakaye

Choose other languages: