Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #140 Translated in Yoruba

فَانْتَقَمْنَا مِنْهُمْ فَأَغْرَقْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ بِأَنَّهُمْ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَكَانُوا عَنْهَا غَافِلِينَ
Nitori naa, A gbesan lara won, A si te won ri sinu agbami odo nitori pe won pe awon ayah Wa niro. Won si je afonufora nipa re
وَأَوْرَثْنَا الْقَوْمَ الَّذِينَ كَانُوا يُسْتَضْعَفُونَ مَشَارِقَ الْأَرْضِ وَمَغَارِبَهَا الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا ۖ وَتَمَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ الْحُسْنَىٰ عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ بِمَا صَبَرُوا ۖ وَدَمَّرْنَا مَا كَانَ يَصْنَعُ فِرْعَوْنُ وَقَوْمُهُ وَمَا كَانُوا يَعْرِشُونَ
A si jogun awon ibuyo oorun lori ile aye ati ibuwo oorun re, ti A fi ibunkun si, fun awon eniyan ti won foju tinrin. Oro Oluwa Re, t’o dara si ko le awon omo ’Isro’il lori nitori pe won se suuru. A si pa ohun ti Fir‘aon ati ijo re n se nise ati ohun ti won n ko nile run
وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتَوْا عَلَىٰ قَوْمٍ يَعْكُفُونَ عَلَىٰ أَصْنَامٍ لَهُمْ ۚ قَالُوا يَا مُوسَى اجْعَلْ لَنَا إِلَٰهًا كَمَا لَهُمْ آلِهَةٌ ۚ قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ
A mu awon omo ’Isro‘il la agbami odo ja. Nigba naa, won koja lodo awon eniyan kan ti won duro ti awon orisa won. Won si wi pe: “Musa, se orisa kan fun wa, gege bi awon (wonyi) se ni awon orisa kan.” (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju eyin ni ijo alaimokan
إِنَّ هَٰؤُلَاءِ مُتَبَّرٌ مَا هُمْ فِيهِ وَبَاطِلٌ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Dajudaju awon wonyi maa parun lori ohun ti won n se (yii). Iro si ni ohun ti won n se nise.”
قَالَ أَغَيْرَ اللَّهِ أَبْغِيكُمْ إِلَٰهًا وَهُوَ فَضَّلَكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ
(Anabi) Musa so pe: "Se ki emi tun ba yin wa olohun kan ti eyin yoo maa josin fun leyin Allahu ni? Oun l’O si se ajulo oore fun yin lori awon eda (asiko yin)

Choose other languages: