Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Ayahs #39 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ تَرَكْنَا مِنْهَا آيَةً بَيِّنَةً لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Dajudaju A ti fi ami kan t’o foju han lele ninu re fun ijo t’o ni laakaye
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَارْجُوا الْيَوْمَ الْآخِرَ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
A tun ranse si ara ilu Modyan. (A ran) arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb (nise si won). O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E reti Ojo Ikeyin, ki e si ma sebaje lori ile ni ti obileje.”
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Won pe e ni opuro. Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
وَعَادًا وَثَمُودَ وَقَدْ تَبَيَّنَ لَكُمْ مِنْ مَسَاكِنِهِمْ ۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَكَانُوا مُسْتَبْصِرِينَ
(A tun ranse si awon) ara ‘Ad ati ara Thamud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si seri won kuro ninu esin (Allahu). Won si je oluriran (nipa oro aye)
وَقَارُونَ وَفِرْعَوْنَ وَهَامَانَ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُمْ مُوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانُوا سَابِقِينَ
(A tun ranse si awon) Ƙorun, Fir‘aon ati Hamon. Dajudaju (Anabi) Musa mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won si segberaga lori ile. Won ko si le mori bo ninu iya

Choose other languages: