Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anbiya Ayahs #105 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ سَبَقَتْ لَهُمْ مِنَّا الْحُسْنَىٰ أُولَٰئِكَ عَنْهَا مُبْعَدُونَ
Dajudaju awon ti rere ti siwaju fun lati odo Wa, awon wonyen ni A oo gbe jinna si Ina
لَا يَسْمَعُونَ حَسِيسَهَا ۖ وَهُمْ فِي مَا اشْتَهَتْ أَنْفُسُهُمْ خَالِدُونَ
Won ko si nii gbo kikun re. Olusegbere si ni won ninu igbadun ti emi won n fe
لَا يَحْزُنُهُمُ الْفَزَعُ الْأَكْبَرُ وَتَتَلَقَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ هَٰذَا يَوْمُكُمُ الَّذِي كُنْتُمْ تُوعَدُونَ
Ipaya t’o tobi julo ko nii ba won ninu je. Awon molaika yoo maa pade won, (won yoo so pe): “Eyi ni ojo yin ti A n se ni adehun fun yin.”
يَوْمَ نَطْوِي السَّمَاءَ كَطَيِّ السِّجِلِّ لِلْكُتُبِ ۚ كَمَا بَدَأْنَا أَوَّلَ خَلْقٍ نُعِيدُهُ ۚ وَعْدًا عَلَيْنَا ۚ إِنَّا كُنَّا فَاعِلِينَ
(Ojo naa ni) ojo ti A maa ka sanmo bi kika ewe tira. Gege bi A ti se bere iseda eda ni ibere pepe (ibe naa ni) A oo da a pada si. (O je) adehun ti A se. Dajudaju Awa maa se bee
وَلَقَدْ كَتَبْنَا فِي الزَّبُورِ مِنْ بَعْدِ الذِّكْرِ أَنَّ الْأَرْضَ يَرِثُهَا عِبَادِيَ الصَّالِحُونَ
Ati pe A ti ko o sinu awon ipin-ipin Tira (ti A sokale) leyin (eyi ti o wa ninu) Tira Ipile (iyen, Laohul-Mahfuth) pe dajudaju ile (Ogba Idera), awon erusin Mi, awon eni rere, ni won yoo jogun re

Choose other languages: