Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #6 Translated in Yoruba

وَاتَّبِعْ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Tele ohun ti A n mu wa fun o ni imisi lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise
وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Ki o si gbarale Allahu. Allahu si to ni Oluso
مَا جَعَلَ اللَّهُ لِرَجُلٍ مِنْ قَلْبَيْنِ فِي جَوْفِهِ ۚ وَمَا جَعَلَ أَزْوَاجَكُمُ اللَّائِي تُظَاهِرُونَ مِنْهُنَّ أُمَّهَاتِكُمْ ۚ وَمَا جَعَلَ أَدْعِيَاءَكُمْ أَبْنَاءَكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ قَوْلُكُمْ بِأَفْوَاهِكُمْ ۖ وَاللَّهُ يَقُولُ الْحَقَّ وَهُوَ يَهْدِي السَّبِيلَ
Allahu ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ikun re. (Allahu) ko si so awon iyawo yin, ti e n fi eyin won we eyin iya yin, di iya yin. Ati pe (Allahu) ko so awon omo-olomo ti e n pe ni omo yin di omo yin. Iyen ni oro enu yin. Allahu n so ododo. Ati pe Oun l’O n fi (eda) mona
ادْعُوهُمْ لِآبَائِهِمْ هُوَ أَقْسَطُ عِنْدَ اللَّهِ ۚ فَإِنْ لَمْ تَعْلَمُوا آبَاءَهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ وَمَوَالِيكُمْ ۚ وَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ فِيمَا أَخْطَأْتُمْ بِهِ وَلَٰكِنْ مَا تَعَمَّدَتْ قُلُوبُكُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
E pe won pelu oruko baba won. Ohun l’o se deede julo lodo Allahu, sugbon ti e o ba mo (oruko) baba won, omo iya yin ninu esin ati eru yin kuku ni won. Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba sasise re, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
النَّبِيُّ أَوْلَىٰ بِالْمُؤْمِنِينَ مِنْ أَنْفُسِهِمْ ۖ وَأَزْوَاجُهُ أُمَّهَاتُهُمْ ۗ وَأُولُو الْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِي كِتَابِ اللَّهِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُهَاجِرِينَ إِلَّا أَنْ تَفْعَلُوا إِلَىٰ أَوْلِيَائِكُمْ مَعْرُوفًا ۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي الْكِتَابِ مَسْطُورًا
Anabi ni eto si awon onigbagbo ododo ju emi ara won lo (nipa ife re ati idajo re). Awon aya re si ni iya won. Ninu Tira Allahu, awon ebi, apa kan won ni eto si ogun jije ju apa kan lo. (Awon ebi tun ni eto si ogun jije) ju awon onigbagbo ododo ati awon t’o kuro ninu ilu Mokkah fun aabo esin, afi ti e ba maa se daadaa kan si awon ore yin (wonyi ni ogun le fi kan won pelu asoole). Iyen wa ninu Tira (Laohul-Mahfuth) ni akosile

Choose other languages: