Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #183 Translated in Yoruba

مَا كَانَ اللَّهُ لِيَذَرَ الْمُؤْمِنِينَ عَلَىٰ مَا أَنْتُمْ عَلَيْهِ حَتَّىٰ يَمِيزَ الْخَبِيثَ مِنَ الطَّيِّبِ ۗ وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُطْلِعَكُمْ عَلَى الْغَيْبِ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَجْتَبِي مِنْ رُسُلِهِ مَنْ يَشَاءُ ۖ فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ ۚ وَإِنْ تُؤْمِنُوا وَتَتَّقُوا فَلَكُمْ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Allahu ko nii gbe awon onigbagbo ododo ju sile lori ohun ti e wa lori re (nibi aimo onigbagbo ododo loto yato si sobe-selu) titi O maa fi ya eni buruku soto kuro lara eni daadaa. Allahu ko si nii fi imo ikoko mo yin, sugbon Allahu yoo sesa eni ti O ba fe ninu awon Ojise Re. Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Ti e ba gbagbo ni ododo, ti e si beru (Allahu), esan nla yo si wa fun yin
وَلَا يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ يَبْخَلُونَ بِمَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ هُوَ خَيْرًا لَهُمْ ۖ بَلْ هُوَ شَرٌّ لَهُمْ ۖ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُوا بِهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ وَلِلَّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Ki awon t’o n sahun pelu ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re ma se lero pe oore ni fun won. Rara, aburu ni fun won. A o fi ohun ti won fi sahun di won lorun ni Ojo Ajinde. Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
لَقَدْ سَمِعَ اللَّهُ قَوْلَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ فَقِيرٌ وَنَحْنُ أَغْنِيَاءُ ۘ سَنَكْتُبُ مَا قَالُوا وَقَتْلَهُمُ الْأَنْبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَنَقُولُ ذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ
Allahu kuku ti gbo oro awon t’o wi pe: “Dajudaju alaini ni Allahu, awa si ni oloro.” A maa sakosile ohun ti won wi ati pipa ti won pa awon Anabi lai letoo. A si maa so pe: “E to iya Ina jonijoni wo.”
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ
Iyen (ri bee) nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re)
الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ عَهِدَ إِلَيْنَا أَلَّا نُؤْمِنَ لِرَسُولٍ حَتَّىٰ يَأْتِيَنَا بِقُرْبَانٍ تَأْكُلُهُ النَّارُ ۗ قُلْ قَدْ جَاءَكُمْ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِي بِالْبَيِّنَاتِ وَبِالَّذِي قُلْتُمْ فَلِمَ قَتَلْتُمُوهُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Awon t’o wi pe: "Dajudaju Allahu sadehun fun wa pe a o gbodo gba Ojise kan gbo titi o maa fi mu saraa kan wa fun wa ti ina (atorunwa) yoo fi lanu." So pe: "Dajudaju awon Ojise kan ti wa ba yin siwaju mi pelu awon eri to yanju ati eyi ti e wi (yii), nitori ki ni e fi pa won ti e ba je olododo

Choose other languages: