Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #136 Translated in Yoruba

وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Ki e tele ti Allahu ati Ojise nitori ki A le ke yin
وَسَارِعُوا إِلَىٰ مَغْفِرَةٍ مِنْ رَبِّكُمْ وَجَنَّةٍ عَرْضُهَا السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ أُعِدَّتْ لِلْمُتَّقِينَ
E yara wa aforijin lodo Oluwa yin ati Ogba Idera kan, eyi ti ibu re to awon sanmo ati ile, ti Won pa lese sile fun awon oluberu (Allahu)
الَّذِينَ يُنْفِقُونَ فِي السَّرَّاءِ وَالضَّرَّاءِ وَالْكَاظِمِينَ الْغَيْظَ وَالْعَافِينَ عَنِ النَّاسِ ۗ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ
Awon t’o n na owo won nigba idera ati nigba inira, awon ti n gbe ibinu mi, awon alamojuukuro fun awon eniyan nibi asise; Allahu nifee awon oluse-rere
وَالَّذِينَ إِذَا فَعَلُوا فَاحِشَةً أَوْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ ذَكَرُوا اللَّهَ فَاسْتَغْفَرُوا لِذُنُوبِهِمْ وَمَنْ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا اللَّهُ وَلَمْ يُصِرُّوا عَلَىٰ مَا فَعَلُوا وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Awon ti (o je pe) nigba ti won ba se ibaje kan tabi ti won ba sabosi si emi ara won, won a ranti Allahu, won a si toro aforijin fun ese won, - Ta si ni O n fori awon ese jin (eda) bi ko se Allahu. Won ko si taku sori ohun ti won se nigba ti won mo (pe ese ni)
أُولَٰئِكَ جَزَاؤُهُمْ مَغْفِرَةٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَجَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَنِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ
Awon wonyen, esan won lodo Oluwa won ni aforijin ati awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan oluse-ise rere si dara

Choose other languages: